Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 18:3-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀ta mi!’

4. “Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn: ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúṣàájú ènìyàn,

5. Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má baà fi wíwá rẹ̀ nígbákùúgbà dá mi lágara.’ ”

6. Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí!

7. Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn?

8. Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”

9. Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀le ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn;

10. Pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹ́ḿpílì láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisí, èkejì sì jẹ́ agbowó òde.

11. Èyí Farisí dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.

12. Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́ṣẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’

13. “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’

14. “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”

15. Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè fi ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí.

Ka pipe ipin Lúùkù 18