Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 18:29-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run,

30. Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”

31. Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn.

32. Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ si i lára.

33. Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á: ní ijọ́ kẹ́ta yóò sì jíǹde.”

34. Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn: ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.

35. Bí ó ti súnmọ́ Jẹ́ríkò, afọ́jú kan jókòó lẹ́bá ọ̀nà ó ń ṣagbe:

36. Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó bèèrè pé, kíni a lè mọ èyí sí.

37. Wọ́n sì wí fún un pé, “Jésù ti Násárẹ́tì ni ó ń kọjá lọ.”

38. Ó sì kígbe pé, “Jésù, ìwọ ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi!”

39. Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi!”

40. Jésù sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í,

41. Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”

42. Jésù sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”

43. Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.

Ka pipe ipin Lúùkù 18