Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 18:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì pa òwe kan fún wọn nítorí èyí yìí pé, ó yẹ kí a má a gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀;

2. Wí pé, “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúṣàáájú ènìyàn.

3. Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀ta mi!’

4. “Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn: ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúṣàájú ènìyàn,

5. Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má baà fi wíwá rẹ̀ nígbákùúgbà dá mi lágara.’ ”

6. Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí!

7. Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn?

8. Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”

9. Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀le ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn;

10. Pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹ́ḿpílì láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisí, èkejì sì jẹ́ agbowó òde.

11. Èyí Farisí dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.

Ka pipe ipin Lúùkù 18