Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 17:9-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Òun ó ha máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pa láṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀.

10. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í se iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwá ti ṣe.’ ”

11. Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerúsálémù, ó kọjá láàrin Samaríà òun Gálílì.

12. Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè:

13. Wọ́n sì nahùn sókè, wí pé, “Jésù, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”

14. Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.

15. Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun lára dá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo.

16. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samáríà ni òun í ṣe.

17. Jésù sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà?

18. A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?”

19. Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá.”

20. Nígbà tí àwọn Farisí bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, “Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú àmì:

21. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, ‘Kíyèsí i níhìn ín!’ tàbí ‘Kíyèsí i lọ́hùn ún ni!’ sáà wòó, ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínú yín.”

22. Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin óò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ ọmọ ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i.

23. Wọ́n sì wí fún yín pé, ‘Wò ó níhìnín;’ tàbí ‘Wò ó lọ́hùn ún!’ Ẹ máa lọ, ẹ má se tẹ̀lé wọn.

24. Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apákan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀.

25. Ṣùgbọ́n kò lè sàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.

Ka pipe ipin Lúùkù 17