Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 17:5-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àwọn àpósítélì sì wí fún Olúwa pé, “Bùsí ìgbàgbọ́ wa.”

6. Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn músítadì, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi Músítádì yìí pé, ‘Kí a fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú òkun,’ yóò sì gbọ́ ti yín.

7. “Ṣùgbọ́n tani nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójú kan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jòkòó láti jẹun’?

8. Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’?

9. Òun ó ha máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pa láṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀.

10. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í se iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwá ti ṣe.’ ”

11. Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerúsálémù, ó kọjá láàrin Samaríà òun Gálílì.

12. Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè:

13. Wọ́n sì nahùn sókè, wí pé, “Jésù, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”

14. Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.

15. Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun lára dá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo.

16. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samáríà ni òun í ṣe.

17. Jésù sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà?

18. A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?”

19. Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá.”

20. Nígbà tí àwọn Farisí bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, “Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú àmì:

Ka pipe ipin Lúùkù 17