Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 17:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa dé: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ dé.

2. Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀

3. Ẹ máa kíyèsíra yín.“Bí arákùnrin rẹ bá sẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dárí jìn ín.

4. Bí ó bá sì sẹ̀ ọ́ ní ẹ̀rìnméje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ẹ̀rẹ̀méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dárí jìn ín.”

5. Àwọn àpósítélì sì wí fún Olúwa pé, “Bùsí ìgbàgbọ́ wa.”

6. Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn músítadì, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi Músítádì yìí pé, ‘Kí a fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú òkun,’ yóò sì gbọ́ ti yín.

7. “Ṣùgbọ́n tani nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójú kan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jòkòó láti jẹun’?

8. Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’?

Ka pipe ipin Lúùkù 17