Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 16:13-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “Kò sí ìránṣẹ́ kan tí ó le sin olúwa méjì: àyàfi kí ó kórìíra ọ̀kan, yóò sì fẹ́ èkejì; tàbí yóò fi ara mọ́ ọ̀kan yóò sì yan èkejì ní ìpọ̀sì. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run pẹ̀lú mámónì.”

14. Àwọn Farisí, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ sùtì sí i.

15. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni àwọn tí ń dáre fún ara yín níwájú ènìyàn; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn yín: nítorí èyí tí a gbé níyìn lọ́dọ̀ ènìyàn, ìríra ni níwájú Ọlọ́run.

16. “Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Jòhánù: Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀.

17. Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí sóńsó kan ti òfin kí ó yẹ̀.

18. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà: ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé, ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.

19. “Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ asọ elésèé àlùkò àti asọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójóojúmọ́:

20. Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lásárù, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju,

21. Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.

22. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn ańgẹ́lì gbé e lọ sí oókan-àyà Ábúráhámù: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;

23. Ní ipò-òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìṣẹ́ oró, ó sì rí Ábúráhámù ní òkèrè, àti Lásárù ní oókan-àyà rẹ̀.

24. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Ábúráhámù, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lásárù, kí ó tẹ oríka rẹ̀ bọmi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’

25. “Ṣùgbọ́n Ábúráhámù wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lásárù ohun búburú: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.

26. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má baa le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’

27. “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán an lọ sí ilé baba mi:

28. Nítorí mo ní arákùnrin márùnún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má baa wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’

29. “Ábúráhámù sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mósè àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ ti wọn.’

30. “Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ábúráhámù baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’

Ka pipe ipin Lúùkù 16