Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 16:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun-ìní rẹ̀ ṣòfò.

2. Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mọ́.’

3. “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò lè walẹ̀; láti sàgbẹ̀ ojú ń tì mí.

4. Mo mọ èyí tí èmi yóò se, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi isẹ́ ìríjú, kí wọn kí ó le gbà mí sínú ilé wọn.’

5. “Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’

6. “Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún Òṣùwọ̀n òróró.’“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta.’

7. “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ́ jẹ?’“Òun sì wí pé, ‘Ọgọ́rùnún òsùwọ̀n àlìkámà.’“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin.’

8. “Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é: àwọn ọmọ ayé yìí sáà gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.

9. Èmi sì wí fún yín, ẹ fi mámónì àìṣòótọ́ yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí yóò bá yẹ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé.

Ka pipe ipin Lúùkù 16