Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 14:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

20. “Ẹ̀kẹ́ta sì wí pé, ‘Mo sẹ̀sẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’

21. “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpòpò ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúkùn-ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’

22. “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, àyè sì ń bẹ síbẹ̀.’

23. “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún.

24. Nítorí mo wí fún yín, Ẹnìkẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́ wò nínú àsè ńlá mi!’ ”

25. Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé,

26. “Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kóríra bàbá rẹ̀, àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.

27. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.

28. “Nítorí tani nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jòkòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀.

29. Kí ó má baà jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà.

Ka pipe ipin Lúùkù 14