Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 13:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Gálílì fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pílátù dàpọ̀ mọ́ ti wọn.

2. Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Gálílì wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Gálílì lọ, nítorí wọ́n jẹ iru ìyà báwọ̀n-ọ́n-nì?

3. Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò se pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

4. Tàbí àwọn méjìdínlógún, tí ilé-ìsọ́ ní Sílóámù wólù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin sebí wọ́n ṣe ẹlẹ́sẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerúsálémù lọ?

5. Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”

6. Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé: “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan.

7. Ó sì wí fún olùsọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sáàwòó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’

8. “Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ lí ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i:

9. Bí ó bá sì so èso, gẹ́gẹ́: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”

10. Ó sì ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù kan ní ọjọ́ ìsinmi.

11. Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹmí àìlera, láti ọdún méjìdínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe.

12. Nígbà tí Jésù rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.”

13. Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.

14. Olórí sínágọ́gù sì kún fún ìrúnnú, nítorí tí Jésù múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, Ijọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́: nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má se ní ọjọ́ ìsinmi.

Ka pipe ipin Lúùkù 13