Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 12:50-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

50. Ṣùgbọ́n èmi ní bamtísíìmù kan tí a ó fi bamitisí mi; ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí!

51. Ẹ̀yin ṣe bí àlààáfíà ni èmi wá fi sáyé? Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa.

52. Nítorí láti ìsinsìn yìí lọ, ènìyàn márùn-ún yóò wà ní ilé kan náà tí a ó yà ní ipa, mẹ́ta sí méjì, àti méjì sí mẹ́ta.

53. A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba; ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.”

54. Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìkùukù àwọ̀sánmà tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, ‘Ọ̀wàrà òjò ń bọ̀,’ a sì rí bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Lúùkù 12