Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 1:34-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Nígbà náà ni Màríà bèèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tii mọ ọkùnrin.”

35. Ańgẹ́lì náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, àti agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò sìji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é.

36. Sì kíyèsí i, Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọ kùnrin kan ní ògbólògbó rẹ̀: èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn.

37. Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”

38. “Màríà sì dáhùn wí pé, wò ó ọmọ-ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ.

39. Ní ijọ́ wọ̀nyí ni Màríà sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Júdà;

40. Ó sì wọ ilé Sakaráyà lọ ó sì kí Èlísabẹ́tì.

41. Ó sì ṣe, nígbà tí Èlísábẹ́tì gbọ́ kíkí Màríà, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Èlísábẹ́tì sì kún fún Èmí mímọ́;

42. Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alúbùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkúnfún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí.

43. Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá?

44. Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀.

45. Alábùkúnfún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́: nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”

Ka pipe ipin Lúùkù 1