Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kólósè 3:10-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé titun wọ̀, èyí tí a sọ di titun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dáa.

11. Níbi tí kò gbé sí Gíríkì tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìnímọ̀, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kírísítì ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

12. Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìsoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù.

13. Ẹ máa fara dàá fún ara yín, ẹ sì máa dáríji ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kírísítì ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú.

14. Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.

15. Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́.

16. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kírísítì máa gbé inú yín lí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ sì máa gba ara yín, níyànjú nínú Sáàmù, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa fi oore ọ̀fẹ́ kọrin ní ọkàn yín sí Olúwa

17. Ohunkóhun tí ẹ̀yín bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jésù Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run baba nípasẹ̀ rẹ̀.

18. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.

19. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn.

20. Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo: nítorí èyí dára gidigi nínú Olúwa.

21. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.

22. Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrojú ṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣugbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run:

23. Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn;

24. Kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè ogun: nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kírísítì.

25. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo, yóò gbàá padà nítorí àìṣòdodo náà tí ó ti ṣe: kò sì sí ojúṣáájú.

Ka pipe ipin Kólósè 3