Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kólósè 2:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí nínú Kírísítì ni àti rí ẹ̀kún ìwà Ọlọ́run ní ipò ara,

10. ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kírísítì, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ.

11. Nínú ẹni tí a kò fí ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní Ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kírísítì.

12. Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.

13. Àti ẹ̀yin, ẹni tí o ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ni, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín;

14. Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn-án a mọ àgbélébùú;

15. Ó sì ti já àwọn aláṣẹ àìrí àti àwọn alágbára, ó ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn nínú rẹ̀.

16. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àṣẹ, tàbí oṣù titun, àtì ọjọ́ ìsinmi:

17. Àwọn tí í ṣe òjìjí ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ti Kírísítì ni ara.

18. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn ańgẹ́lì lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nipa èrò ti ọkan ara rẹ̀.

19. Tí kò sì di orí nì kú ṣinṣin, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ́kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.

20. Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kírísítì kúrò nínú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin ń tẹ́ríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé,

21. Má ṣe dìímú, má se tọ́ ọ wò, má ṣe fọwọbàá,

22. Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn?

23. Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, ni àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọn-ara-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè hàn nínú fún ìfẹ́kúfẹ ara.

Ka pipe ipin Kólósè 2