Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kólósè 1:9-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò yéé gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípaṣẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí

10. Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹlẹ́gbẹ́ irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà ninú ìmọ̀ Ọlọ́run.

11. pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀ṣíwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.

12. Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yin láti jẹ́ alábàápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀.

13. Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn.

14. Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, ìdàríjì ẹ̀sẹ̀.

15. Kírísítì ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.

16. Nítorì nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un.

17. Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ sọ̀kan.

18. Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí Òun lè ní ipo tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun.

19. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun lè máa gbé nínú rẹ̀.

20. Àti nípaṣẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ lọ́rùn, nípa mímú àlàáfíà wá nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélèbùú.

21. Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín.

Ka pipe ipin Kólósè 1