Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Júdà 1:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. JÚDÀ, ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì àti arákùnrin Jákọ́bù,Sí àwọn tí a pè, olùfẹ́ nínú Ọlọ́run Baba, tí a pamọ́ fún Jésù Kírísítì:

2. Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

3. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.

4. Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọn ń yọ́ wọlé, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń ṣẹ́ Olúwa wa kansoso náà, àní Jésù Kírísítì Olúwa.

5. Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́.

6. Àti àwọn ańgẹ́lì tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìṣàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ ọjọ́ ńlá nì.

7. Àní bí Sódómù àti Gomorà, àti àwọn ìlú agbégbé wọn, ti fi ara wọn fún àgbérè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun.

8. Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjoye, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búbúrú sí àwọn ọlọ́lá.

9. Ṣùgbọ́n Mákẹ́lì, olórí awọn ańgẹ́lì, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítórí òkú Mósè, kò sọ ọ̀rọ̀ òdì sí i; Ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.”

10. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀ òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa ìròfún-ara, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípaṣẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.

11. Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Káínì, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìsìnà Bálámù nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kórà.

12. Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àṣè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùsọ́ àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọn tú ti-gbòǹgbò-ti-gbòǹgbò.

Ka pipe ipin Júdà 1