Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 8:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ̀, ó nà rọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.”

8. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.

9. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí-ọkan wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jésù nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàárin, níbi tí ó wà.

10. Jésù sì nà rọ́, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”

11. Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.”Jésù wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: má a lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́sẹ̀ mọ́.”

12. Jésù sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

13. Nítorí náà àwọn Farisí wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”

14. Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ.

15. Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.

16. Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi.

17. A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì.

18. Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rí mi.”

Ka pipe ipin Jòhánù 8