Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 6:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.

3. Jésù sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀.

4. Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì sún mọ́ etílé.

5. Ǹjẹ́ bí Jésù ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Fílípì pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?”

6. Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.

7. Fílípì dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ níí rí ju díẹ̀ bù jẹ.”

8. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù wí fún un pé,

9. “Ọmọdékùnrin kan ńbẹ níhínyìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùnún àti ẹja kékèké méjì: ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”

10. Jésù sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Kóríkó púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye.

11. Jésù sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọn bí wọ́n ti ń fẹ́.

Ka pipe ipin Jòhánù 6