Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 5:5-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjìdínlógójì.

6. Bí Jésù ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”

7. Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ ṣíwájú mi.”

8. Jésù wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.”

9. Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn.Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.

10. Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.”

11. Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ”

12. Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”

13. Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jésù ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.

14. Lẹ́yìn náà, Jésù rí i ní tẹ́ḿpìlì ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má se dẹ́sẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”

15. Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jésù ni ẹni tí ó mú òun láradá.

16. Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jésù, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí Ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.

17. Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”

18. Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.

19. Nígbà náà ni Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò se ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Jòhánù 5