Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 5:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọ àwọn Júù kan kò; Jésù sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù.

2. Adágún omi kan sì wà ní Jérúsálẹ́mù, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Bẹtiṣáídà ní èdè Hébérù, tí ó ní ìloro márùn-ún.

3. Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dúbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti alárùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi.

4. Nítorí angẹ́lì a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú àrùnkárùn tí ó ní.

5. Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjìdínlógójì.

6. Bí Jésù ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”

7. Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ ṣíwájú mi.”

8. Jésù wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.”

9. Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn.Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.

10. Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.”

11. Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ”

12. Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”

Ka pipe ipin Jòhánù 5