Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 4:42-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Krísítì náà, Olùgbàlà aráyé.”

43. Lẹ́yìn ijọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Gálílì.

44. (Nítorí Jésù tìkararẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ Òun tìkárarẹ̀.)

45. Nítorí náà nígbà tí ó dé Gálílì, àwọn ará Gálílì gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jérúsálẹ́mù nígbà àjọ; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.

46. Bẹ́ẹ̀ ni Jésù tún wá sí Kánà ti Gálílì, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kápérnámù.

47. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jésù ti Jùdéà wá sí Gálílì, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.

48. Nígbà náà ni Jésù wí fún u pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí àmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”

49. Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”

50. Jésù wí fún un pé, “Má a bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”

51. Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàde rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè.

52. Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí kéje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”

53. Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ọmọ rẹ̀ yè: Òun tìkara rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.

54. Èyí ni iṣẹ́ àmì kéjì tí Jésù ṣe nígbà tí ó ti Jùdéà jáde wá sí Gálílì.

Ka pipe ipin Jòhánù 4