Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 4:38-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”

39. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.”

40. Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samáríà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ijọ́ méjì.

41. Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

42. Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Krísítì náà, Olùgbàlà aráyé.”

43. Lẹ́yìn ijọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Gálílì.

44. (Nítorí Jésù tìkararẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ Òun tìkárarẹ̀.)

45. Nítorí náà nígbà tí ó dé Gálílì, àwọn ará Gálílì gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jérúsálẹ́mù nígbà àjọ; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.

46. Bẹ́ẹ̀ ni Jésù tún wá sí Kánà ti Gálílì, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kápérnámù.

47. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jésù ti Jùdéà wá sí Gálílì, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.

48. Nígbà náà ni Jésù wí fún u pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí àmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”

Ka pipe ipin Jòhánù 4