Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 3:19-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú.

20. Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú níí ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kìí sí wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí.

21. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ níí wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”

22. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Jùdíà; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni.

23. Jòhánù pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Áhínónì, ní agbégbé Sálímù, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọmi.

24. Nítorí tí a kò tí ì sọ Jòhánù sínú túbú.

25. Nígbà náà ni iyàn kan wà láàárin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù, àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù.

26. Wọ́n sì tọ Jòhánù wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rábì, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jọ́dánì, tí ìwọ ti jẹ́rí rẹ̀, wò ó, òun tẹ ni bọmi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”

27. Jòhánù dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí ǹkankan gbà, bí kò ṣepé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá.

28. Èyin fúnra yín jẹ́rìí mi, pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kírísítì náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi ṣíwájú rẹ̀.’

29. Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún.

30. Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàì má relẹ̀.

31. “Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ.

32. Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀.

33. Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olótìítọ́ ni Ọlọ́run.

34. Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke.

35. Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́

36. Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”

Ka pipe ipin Jòhánù 3