Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kẹ́ta, a ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kánà ti Gálílì. Ìyá Jésù sì wà níbẹ̀,

2. A sì pe Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà.

3. Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jésù wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”

4. Jésù fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èése tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”

5. Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”

6. Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ogójì gálọ́ọ̀nù.

Ka pipe ipin Jòhánù 2