Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 19:17-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí náà, wọ́n mú Jésù, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnra rẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Hébérù tí à ń pè ní Gọlígọtà:

18. Níbití wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jésù sì wà láàárin.

19. Pílátù sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi í lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni, JÉSÙ TI NÁSÁRẸ́TÌ ỌBA ÀWỌN JÚÙ.

20. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí: nítorí ibi tí a gbé kan Jésù mọ́ àgbélébùú sún mọ́ etí ìlú: a sì kọ ọ́ ní èdè Hébérù àti Látìnì, àti ti Gíríkì.

21. Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pílátù pé, “Má ṣe kọ, ‘Ọba àwọn Júù;’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni Ọba àwọn Júù.”

22. Pílátù dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.

23. Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun, nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apákan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúrán, wọ́n hun ún láti òkè títí jáde.

24. Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé-mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,“Wọ́n pín aṣọ mi láàárin ara wọn,wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ogun ṣe.

25. Ìyá Jésù àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Màríà aya Kílópà, àti Màríà Magidalénì sì dúró níbi àgbélébùú,

26. Nígbà tí Jésù rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!”

27. Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.

28. Lẹ́yìn èyí, bí Jésù ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.”

Ka pipe ipin Jòhánù 19