Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 18:25-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ṣùgbọ́n Símónì Pétérù dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”Ó sì ṣẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”

26. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Pétérù gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?”

27. Pétérù tún ṣẹ́: lójú kan náà àkùkọ sì kọ.

28. Nígbà náà, wọ́n fa Jésù láti ọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́: ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkara wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá.

29. Nítorí náà Pílátù jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá sí ọkùnrin yìí?”

30. Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”

31. Nítorí náà Pílátù wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.”Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, “Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”

32. Kí ọ̀rọ̀ Jésù ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.

33. Nítorí náà Pílátù tún wọ inú gbọ̀ngàn, ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jésù, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ há ni a ni Ọba àwọn Júù bí?”

34. Jésù dáhùn pé, “Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi?”

35. Pílátù dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́: kín ní ìwọ ṣe?”

36. Jésù dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí: ìbáṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má baà fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”

37. Nítorí náà Pílátù wí fún un pé, “Ọba ni ó nígbà náà?”Jésù dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, Ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”

38. Pílátù wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.

39. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá: nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá Ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”

40. Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Bárábà!” Ọlọ́sà sì ni Bárábà.

Ka pipe ipin Jòhánù 18