Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 16:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti rí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé.

22. Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsìn yìí: ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín.

23. Àti ní ijọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá bèèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín.

24. Títí di ìsinyìí ẹ kò tíì bèèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ bèèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.

25. “Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ ti Baba fún yín gbangba.

26. Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi: èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó bèèrè lọ́wọ́ Baba fún yín:

27. Nítorí tí Baba tìkara rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá.

28. Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé: ẹ̀wẹ̀, mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.”

29. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe.

30. Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”

31. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí?

32. Kíyèsí i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀: ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.

Ka pipe ipin Jòhánù 16