Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 14:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.

13. Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, oun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ.

14. Bí ẹ̀yin bá bèèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.

15. “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́.

16. Nígbà náà èmi yóò wá bèèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé

17. Òun ni Ẹ̀mí Mímọ́ òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Ṣé ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀.

18. Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Òlùtùnú, kí ẹ wá dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀.

19. Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi: nítorí tí èmi wà láàyè, ẹ̀yin ó wà láàyè pẹ̀lú.

20. Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín.

21. Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi: ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”

22. Júdásì (Kì í se Isíkaríótù) wí fún un pé, “Olúwa, èé ha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráye?”

23. Jésù dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀.

24. Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.

25. “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé.

Ka pipe ipin Jòhánù 14