Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 12:33-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣàpẹrẹ irú ikú tí òun ó kú.

34. Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kírísítì wà títí láéláé: ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè? Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí’?”

35. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàárin yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín: ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun gbé ń lọ.

36. Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀!” Nǹkan wọ̀nyí ni Jésù sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn.

37. Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́.

38. Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Ìsàíàh lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé:“Olúwa, tani ó gba ìwàásù wa gbọ́Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”

39. Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Ìsáyà sì tún sọ pé:

40. “Ó ti fọ́ wọn lójú,Ó sì ti sé àyà wọn le;Kí wọn má baà fi ojú wọn rí,Kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,Kí wọn má baà yípadà, kí wọn má baà mú wọn láradá.”

41. Nǹkan wọ̀nyí ni Ìsáyà wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

42. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisí wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sínágọ́gù:

43. Nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.

44. Jésù sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi.

45. Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi.

46. Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.

47. “Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là.

48. Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹ́yìn.

Ka pipe ipin Jòhánù 12