Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 11:41-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jésù sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi.

42. Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn baà lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”

43. Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lásárù, jáde wá.”

44. Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú.Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó má a lọ!”

45. Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Màríà, tí wọ́n rí ohun tí Jésù ṣe, ṣe gbà á gbọ́.

46. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisí lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jésù ṣe.

47. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí pe ìgbìmọ̀ jọ, wọ́n sì wí pé,“Kínni àwa ń ṣe? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì.

48. Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́: àwọn ará Rómù yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.”

49. Ṣùgbọ́n Káyáfà, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá!

50. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó sàǹfàní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má baà ṣègbé.”

51. Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jésù yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà:

Ka pipe ipin Jòhánù 11