Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 11:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn gbangba pé, Lásárù kú,

15. Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀, Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

16. “Nítorí náà Tómásì, ẹni tí à ń pè ní Dídímù, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”

17. Nítorí náà nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ijọ́ mẹ́rin ná,

18. Ǹjẹ́ Bétanì sún mọ́ Jérúsálẹ́mù tó ibùsọ Mẹ́ẹ̀dógún:

Ka pipe ipin Jòhánù 11