Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 10:23-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Jésù sì ń rìn ní tẹ́mpílì, ní ìloro Sólómónì,

24. Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kírísítì náà, wí fún wa gbangba.”

25. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi.

26. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín.

27. Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn:

28. Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi.

29. Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi.

30. Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.”

31. Àwọn Júù sì tún he òkúta, láti sọ lù ú.

32. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?”

33. Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-ọ̀dì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ ṣe Ọlọ́run.”

34. Jésù dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’?

35. Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé-mímọ́ jẹ́,

36. Ẹ̀yin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sí mímọ́, tí ó sì rán sí ayé pé: Ìwọ ń sọ̀rọ̀ òdì, nítorí tí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’

Ka pipe ipin Jòhánù 10