Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 1:38-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Nígbà náà ni Jésù yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ Òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”Wọ́n wí fún un pé, “Rábì” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”

39. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.

40. Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jòhánù, tí ó sì tọ Jésù lẹ́yìn.

41. Ohun àkọ́kọ́ tí Ańdérù ṣe ni láti wá Símónì arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Mèṣáyà” (ẹni tí ṣe Kírísítì).

42. Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jésù.Jésù sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Símónì ọmọ Jónà: Kéfà ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Pétérù).

43. Ní ọjọ́ kéjì Jésù ń fẹ́ jáde lọ sí Gálílì, ó sì rí Fílípì, ó sì wí fún un pé, “Má a tọ̀ mí lẹ́yìn.”

44. Fílípì gẹ́gẹ́ bí i Ańdérù àti Pétérù, jẹ́ ará ìlú Bẹtiṣáídà.

45. Fílípì rí Nàtaníẹ́lì, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mósè kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jésù ti Násárẹ́tì, ọmọ Jósẹ́fù.”

46. Nàtaníẹ́lì béèrè pé, “Násárẹ́tì? Ohun rere kan há lè ti ibẹ̀ jáde?”Fílípì wí fún un pé, “Wá wò ó.”

47. Jésù rí Nàtaníẹ́lì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Ísírẹ́lì tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”

48. Nàtaníẹ́lì béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”Jésù sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Fílípì tó pè ọ́.”

49. Nígbà náà ni Nàtaníẹ́lì sọ ọ́ gbangba pé, “Rábì, Ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”

50. Jésù sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀ jù ìwọ̀nyí lọ.”

Ka pipe ipin Jòhánù 1