Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jákọ́bù 5:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde.

19. Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá sìnà kúrò nińu òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà;

20. Jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́sẹ̀ kan padà kúrò nínú ìsìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Jákọ́bù 5