Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jákọ́bù 5:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ wá nísinsìn yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùn réré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín.

2. Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín.

3. Góòlù òun sílífà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìsúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn.

4. Kíyè sí i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

5. Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa.

6. Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; òun kò kọ ojú ijà sí yín.

7. Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadàwá Olúwa. Kíyèsí i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò.

8. Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀: nítorí ìpadàwá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.

9. Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má baà dá a yín lẹ́bi: kíyè síi, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.

10. Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù.

11. Sáà wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jóòbù, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.

Ka pipe ipin Jákọ́bù 5