Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 7:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Wí pe:“Àmín!Ìbùkún, àti ògo,àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!Àmín!”

13. Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”

14. Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú Ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.

15. Nítorí náà ni,“wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run,tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹḿpílì rẹ̀;ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn.

16. Ebi kì yóò pa wọn mọ́,bẹ́ẹ̀ ni òungbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́;bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọntàbí oorukóoru kan.

17. Nítorí òdọ̀-Àgùntàn tí ń bẹ ni àárin ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe Olùṣọ́-Àgùntàn wọn,tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè:Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 7