Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 22:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ní àárin ìgboro rẹ̀, àti níhà ìkínní kéjì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so oníruurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà.

3. Ègún kì yóò sì sí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín:

4. Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni ìwájú orí wọn.

5. Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lè fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jọba láé àti láéláé.

6. Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran ańgẹ́lì rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”

7. “Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”

8. Èmi, Jòhánù, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ ańgẹ́lì náà, tí o fí nǹkan wọ̀nyí hàn mi,

9. Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”

10. Ó sì wí fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

Ka pipe ipin Ìfihàn 22