Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 22:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí Kírísítalì, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá,

2. Ní àárin ìgboro rẹ̀, àti níhà ìkínní kéjì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so oníruurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà.

3. Ègún kì yóò sì sí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín:

4. Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni ìwájú orí wọn.

5. Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lè fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jọba láé àti láéláé.

6. Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran ańgẹ́lì rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”

7. “Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”

8. Èmi, Jòhánù, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ ańgẹ́lì náà, tí o fí nǹkan wọ̀nyí hàn mi,

9. Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”

10. Ó sì wí fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

11. Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì ṣó: Àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nìṣó: Àti ẹni tí ń ṣe olòdodo, kí ó máa ṣe òdodo nìṣó: Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nìṣó.”

12. “Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí.

13. Èmi ni Álífà àti Òmégà, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.

Ka pipe ipin Ìfihàn 22