Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 21:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Álfà àti Ómégà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí oúngbẹ ń gbẹ láti orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.

7. Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi.

8. Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fí iná àti súfúrù jó: èyí tí i ṣe ikú kéjì.”

9. Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje, tí wọ́n ni ìgò méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìnín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-Àgùntàn hàn ọ́.”

10. Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fí ìlú náà hàn mi, Jerúsálémù mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,

11. Tí ó ní ògo Ọlọ́run: ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasípérì, ó mọ́ bí Kírísítálì;

12. Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu-bodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu-bodè náà áńgẹ́lì méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;

13. Ní ìhá ìlà-oòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu-bodè mẹ́ta; ní ìhà gúsù ẹnu-bodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-òòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta.

14. Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Àpósítélì méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

15. Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu-bodè rẹ̀, àti odi rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìfihàn 21