Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 21:17-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ̀ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí ańgẹ́lì náà.

18. A sì fi Jásípérì mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere.

19. A fi onírúuru òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ ìkínní jẹ́ jásípérì; ìkejì, sáfírù; ìkẹta, kalíkedónì ìkẹrin, emeralídì.

20. Ikarun, sadonikísì; ìkẹfà, kanelíánì; ìkeje, kírisolítì; ìkẹjọ bérílì; ìkẹsan, tọ́pásì; ìkẹwàá, kírísopírasù; ìkọkànlá, jakinítì; ìkejìlá, ámétísítì.

21. Ẹnu-bodè méjèèjìlá jẹ́ pẹ́rílì méjìlá: olúkúlùkù ẹnu-bodè jẹ́ pérílì kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán.

22. Èmi kò sì ri tẹḿpílì nínú rẹ̀: nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni téḿpílì rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

23. Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i: nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀.

24. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀: àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀.

25. A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu-bodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀.

26. Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìfihàn 21