Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 2:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Sàtánì wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Áńtípà ẹlẹ́rì mi, olóòótọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrin yín, níbi tí Sàtánì ń gbé.

14. Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí o di ẹ̀kọ́ Báláámù mú nibẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Bálákì láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá ṣíwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè.

15. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikoláétanì pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra.

16. Nítorí náàonúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsinyìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.

17. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ; Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi mánà tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.

18. “Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára:

Ka pipe ipin Ìfihàn 2