Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 18:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:“Bábílónì ńlá ṣubú! Ó ṣubú!Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù,àti ihò ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo,àti ilé ẹyẹ àìmọ́ gbogbo,àti ti ẹyẹ ìríra.

3. Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ nigbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú.Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè,àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”

4. Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:“Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,kí ẹ ma bàá ṣe alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,kí ẹ ma bàá si ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.

5. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,Ọlọ́run sì ti rántí àìsedédé rẹ̀.

6. San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.

7. Níwọ̀n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó,tí ó sì hùwà wọ̀bìà,níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́;nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé,‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’

8. Nítorí náà, ní ìjọ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,ìkú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;a ó sì fi iná sun ún pátapáta:nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

9. “Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbérè, ti wọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìfihàn 18