Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 16:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ẹ̀kẹrin sì tú ìgò tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára.

9. A sì fi oru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.

10. Ẹ̀karùn-ún sì tú ìgo tirẹ̀ sórí ìtẹ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì sókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora.

Ka pipe ipin Ìfihàn 16