13. Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dírágónì náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá.
14. Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olúdàmarè.
15. “Kíyèsí i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń sọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó mà bàá rìn ni ìhóhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”
16. Ó sì gbá wọn jọ́ sí ìbikan tí a ń pè ní Ámágédónì ní èdè Hébérù.
17. Èkeje si tú ìgo tírẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!”
18. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò sẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tóbẹ́ẹ̀.
19. Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Bábílónì ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un.
20. Olúkúlùkù erekúṣu sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́.
21. Yìnyín ńlá, tí ọkọkan rẹ̀ tó talẹ́ntì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà: Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.