Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 14:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn ń fò ní àárin méjì ọ̀run, pẹ̀lú Ìyìn rere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.

7. Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ogo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbàlẹ́ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti òkun, àti àwọn orísun omi!”

8. Ańgẹ́lì mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “Ó ṣubú, Bábílónì ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”

9. Ańgẹ́lì mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń fóríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀.

10. Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí-wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà láìní àbùlà sínú ago ìrúnnú rẹ̀; a ó sì fi iná sufúrù dá a lóró níwájú àwọn ańgẹ́lì mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn:

Ka pipe ipin Ìfihàn 14