Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 12:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àmì ńlá kan sì hàn ni ọ̀run; obìnrin kan tí a fi òòrùn wọ̀ ní aṣọ, òṣùpá sì ń bẹ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ lórí rẹ̀:

2. Ó sì lóyún, ó sì kígbe ni ìrọbí, ó sì wà ni ìrora àti bímọ.

3. Àmì mìíràn sì hàn lọ́run; sì kíyèsí i, dírágónì pupa ńlá kan, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, àti adé méje ní orí rẹ̀.

4. Ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ó sì jù wọ́n sí ilẹ̀ ayé, dírágónì náà sì dúró níwájú obìnrin náà tí ó fẹ́ bímọ, pé nígbà tí o bá bí i, kí òun lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.

5. Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè: a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀.

6. Obìnrin náà sì sá lọ sí ihà, níbi tí a gbé ti pèṣè ààyè sílẹ̀ dè é láti ọwọ́ Ọlọ́run wá, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta.

7. Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run: Mákẹ́lì àti àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun; dírágónì sì jagun àti àwọn angẹ́lì rẹ̀.

8. Wọ́n kò sì lè ṣẹ́gun; Bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ni ọ̀run.

9. A sì lé dírágónì ńlá náà jáde, ejò láéláé ni, tí a ń pè ni Èṣù, àti Sàtanì, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.

10. Mo sì gbọ́ ohùn rara ní ọ̀run, wí pè:“Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá,àti ọlá àti Kírísítì rẹ̀.Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arakùnrin wa jáde,tí o ń fí wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn-án àti lóru.

11. Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-Àgùntàn náà,àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn,wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀míwọn àní títí dé ikú.

12. Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run,àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn.Ègbé ni fún ayé àti òkun;nítorí Èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá,nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú ṣá ni òun ní.”

13. Nígbà tí dírágónì náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ ayé, ó sè inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà.

14. A sì fi apá iyẹ́ méjì tí ìdì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí ihà, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà.

Ka pipe ipin Ìfihàn 12