Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Sọ́ọ̀lù lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan.

8. Ṣọ́ọ̀lù sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Dámásíkù.

9. Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu.

10. Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Dámásíkù, tí a ń pè ni Ananíyà! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Ananíyà!”Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9