Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí-èémí ìhalẹ̀-mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí alúfà lọ,

2. ó bèèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí sínágọ́gù tí ń bẹ ní ìlú Dámásíkù pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni Ọ̀nà yìí, ìbaà ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerúsálémù.

3. Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súmọ́ Dámásíkù; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọlẹ̀ yí i ká.

4. Ó sì subú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù, è é ṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”

5. Ó sì wí pé, “Ìwọ ta ni, Olúwa?”Olúwa sì wí pé, “Èmi ni Jésù, ẹni ti ìwọ ń ṣe inúnibíni sí; (ohùn ìrora ni fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún).

6. Ó sì ń wárìrì, ẹnu sì yà á, ó ni Olúwa, kín ní ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe? Olúwa sì wí fún pé, Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.”

7. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Sọ́ọ̀lù lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan.

8. Ṣọ́ọ̀lù sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Dámásíkù.

9. Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu.

10. Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Dámásíkù, tí a ń pè ni Ananíyà! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Ananíyà!”Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.”

11. Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Júdà ní Òpópónà Tààrà, kí ó sì bèèrè ẹni tí a ń pè ni Ṣọ́ọ̀lù, ara Tásọ́sì, sá wò ó, ó ń gbàdúrà.

12. Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Ananíyà o wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”

13. Ananíyà sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúrò ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búrukú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerúsálémù.

14. Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhínyìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9