Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.

9. Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Símónì, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaríà. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun.

10. Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ Ńlá.”

11. Wọ́n bọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn.

12. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jésù Kírísítì, a bámítíìsì wọn.

13. Símónì tikararẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bámitíìsì rẹ̀, ó sì tẹ̀ṣíwájú pẹ̀lú Fílípì, ó wo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Fílípì ṣe, ẹnu sì yà á.

14. Nígbà tí àwọn àpósítélì tí ó wà ní Jerúsálémù sí gbọ́ pé àwọn ara Samaríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Pétérù Àti Jòhánù sí wọn.

15. Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́:

16. nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bá lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitíìsì wọn lórúkọ Jésù Olúwa ni.

17. Nígbà náà ni Pétérù àti Jòhánù gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.

18. Nígbà tí Símónì rí i pé nípa gbígbe ọwọ́ leni ni a ń ti ọwọ́ àwọn àpósítélì fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n,

19. ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”

20. Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!

21. Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déedé níwájú Ọlọ́run.

22. Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búrurú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dári ète ọkàn rẹ jì ọ́.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8