Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ní ọjọ́ kejì Mósè yọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun ì bá sí parí rẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; è é ṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’

27. “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ tì Mósè sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ jẹ olórí àti onídàjọ́ wa?

28. Àbí ìwọ ń fẹ́ pa mi gẹ́gẹ́ bí o ti pa ará Íjíbítì lánàá?’

29. Mósè sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Mídíànì, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7